11/09/2012

Omobinrin Fasiti Ibadan gbe majele je nitori okunrin


Omobinrin kan ni ile iwe giga vasiti ti ilu Ibadan gbe bleach Hypo mu ni ojo isinmi ti se ojo kerin, osu kokanla, odun 2012 nitori wipe oko afesona re so wipe oun o se mo. Omobinrin yii ni agbo wipe o wa ni ipele olodun kinni ni  eka imo eto eko ti awon oloyinbo n pe ni Faculty of Art ni ile eko giga vasiti naa.

Ni akoko yii naa si ni awon omo ile eko giga yii n se idanwo won ti saa eto eko
keji lowo ni eyi ti won ti bere
lati bi ose meji seyin ti o si je wipe won yoo pari idanwo won titi opin osu kokanla odun 2012. Iroyin fi to wa leti wipe digba-digba ni won sare gbe omobinrin naa lo si ile iwosan nla UCH ni ilu Ibadan lati le tete doola emi re. Nise ni a tun gbo wipe, iroyin lori wipe kindinrin ti baje ko ja siso ti tan kale kaakiri gbogbo inu ile eko giga naa.

Ni yajo-yajo ni a gbo wipe akorin igbalode kan laarin awon omo ile eko naa ni o ti sare so isele laabi yii di orin kiko ti o pe akole re ni ‘Ife Hypo’ lati fi le ma se kilo-kilo fun awon akegbe re, paapaa julo awon odo’binrin ti n keko laarin won.

Iroyin wa fi to wa leti wipe, omobinrin to gbe bleach Hypo mu yii te pada bo sipo alaafia leyin igba ti won ti ba fo gbogbo majele ti o gbe mu jade ninu ifun re ni ile iwosan ti inu ile eko giga naa ti won n pe ni ‘Jaja’.

Ni kukuru, isele yoo wu to le sele ti o fi wa je wipe majele gbigbe mu wa ni oro was u kan fun omode binrin yii, iwadi si n te siwaju si.

No comments:

Post a Comment