11/12/2012

LAM ADESINA TA TERU NPA NI OMO ODUN METALELAADORIN



Awaye iku kan o si, orun nikan lare mabo. Iku to pa eni ti o ti fi gba kan ri je gomina ipinle Oyo, Alhaji Lamidi Onaolapo Adesina je adanu nla lo je fun ipinle Oyo lapapo ati paapaa julo laarin awon omo egbe oselu ACN ni ipile Oyo.
Won ti sin Lam Adesina ni liana esin Musulumi ni ile re to wa ni Felele ni ilu Ibadan.
Lam ku ni afemojumo ojo isinmi 11-11-2012 ni ile iwosan nla kan ti o je ti aladani ni ilu Eko leyin igba ti won ti du emi re ko ba ku sori aisan ito-sugar ti o ti n se lati ojo pipe seyin.
Ese o gba ero ni ibi isinku okan ninu awon ogbontarigi akinkanju oloselu ni ipinle Oyo.
Won gbe oku re de si ilu Ibadan ninu oko gboku-gboku ti nomba re je LA156A08 ni deede agogo meta koja ogun iseju nigba ti won sig be wo kale lo leyin bi wakati kan ti won gbe oku re de ile re ni Felele.
Nibi isinku re lati ri opolopo awon loko-loko oloselu lati inu opolopo egbe oloselu kaakiri orile ede Naijiriya. Ara won lati ri apenugan ile igbimo asoju-sofin, Amofin Aminu Tambuwal, Adari egbe oselu ACN lapapo ni orile ede wa Naijiriya, Bola Ahmed Tinubu ati alaga egbe naa, Oloye Bisi Akande.
Awon miran ti awon naa tun fara han nibe naa ni gomina ipinle Oyo lowo-lowo, Abiola Ajimobi, Babatunde Raji ti ipinle Eko, Ibikunle Amosun ti ipinle Ogun, Dokita Kayode Fayemi ti ipinle Ekiti ati Ogbeni Rauf Aregbesola ti ipinle Osun.

No comments:

Post a Comment