11/30/2012

Akoni olokiki ninu ere lede Yoruba, Akin Akin Ogungbe ti dagbere f'aye

Erin wo! Ajanaku sun bi oke, ojogbon akoni olokiki ninu ere lede Yoruba fun opolopo odun seyin, Akintola Ogungbe ni a gbo wipe o ti ta teru nipa.

Ilu mooka akoni ati oludari ninu awon elere ni ede Yoruba je omo bibi ipinle Ogun. Ojogbon Akin Ogungbe je omo odun mejidinlogorin (78 years) ki o to fi'le sa'so bo'ra.
Lara awon ere ti o ti se ti o fi di eni ti gbogbo aye n fe tire ni 'Ireke Onibudo', ere nipa itan abalaye ti ati owo ojogbon D.O. Fagunwa ko.

No comments:

Post a Comment