11/27/2012

Iyawo pe oko lejo, o ni ko ba oun ni ajosepo gege bi tokotaya fun odun meewa bayi


Iyawo, Saratu Haruna ni o wo oko re, Isa Mainika wa sile ejo ni ojo aje 26-11-2012 niwaju adajo ni ile ejo ti Sharia keji ti ipinle Kaduna ti o wa ni Magajin Gari wipe oko ti fi eto ibalopo gege bi lokolaya dun oun lati odun keewa si asiko ti a wa yii. Haruna ti n gbe Kawo, ni ijoba ibile Ila oorun ti ilu Kaduna so yanya niwaju ile ejo wipe oun o tire ni ife si ajosepo mo gegebi lokolaya laarin oun ati oko oun mo.


Arabinrin yii ni o so niwaju ile ejo wipe oun o ni igbagbo mo wipe awon si n gbe igbe aye tokotaya mo. O so wipe awon ti jo n gbe papo lati bi odun meewa seyin nigbati ko si si nkankan ti o da awon po ri gege bi tokotaya.

O tesiwaju ninu oro re niwaju ile ejo wipe oun o nife oko oun mo ati wipe bee si ni oun fe ma gbe papo pelu Mainika gege bi oko ati aya mo, “Mi o feran re mo.”

Se agbo ejo enikan da si ni awon Yoruba ma n pe ni agba osika, nigba ti adajo beere lowo Mainika wipe ki wa lo ri lobe to fi wa iru sowo? Nigba naa ni Mainika naa salaye edun okan re sita fun aye gbo. O wipe kii kuku se wipe ohun o fe ma ni ibalopo gege bi tokotaya pelu iyawo oun sugbon iyawo oun ni kii gba ohun laaye lati fara kan oun.

Oun naa tesiwaju ninu oro re wipe, igbakugba ti oun ba bere fun aaye lati sere ife papo pelu iyawo oun, nise ni yoo ko jale. Siwaju si, o tun salaye wipe ojo kan wan ti o je wipe oro a bara eni sun laarin awon mejeeji di ija gidi de bi wipe, nise ni iyawo oun fi eyin da batani si gbogbo ara oun.

Mainika so wipe wahala yii bere lati igba ti iyawo oun ti bi omo eleekeji fun oun. O so wipe lati igba naa oun o mo ohun ti oun se fun ati wipe oun si ti bi leere ni aimoye igba ti iyawo oun ko si fun oun ni esi kankan titi di asiko ti awon wa si ile ejo Sharia yii.

O tun tesiwaju wipe oro naa ti di ohun ti awon agbalagba ti da si sugbon ti ko so eso ire kankan. “Mo si feran re gan-an. N o fe ko sile nitori ojo ola awon omo wa.”

Oro naa toju su adajo Khadi, Mallam Ibrahim Inuwa, idi re leyi to se pa lase fun awon mejeeji wipe ki won gba awon agbalagba laaye lati yanju ikunsinu yoo wu ti ba wa laarin won ni itubi-inubi. Inuwa tesiwaju ninu oro re wipe bi oro naa ko ba wa ni iyanju, nigba naa ni ile ejo Sharia naa yoo wa mo ohun ti yoo se lori oro won.

Khadi so wipe ohun ti o n sele laarin awon mejeeji ko to Sunnah ninu esin Islam. O so wipe ko si aaye fun toko-taya lati ma re ara won je.

Ni ipari, adajo Khadi ti sun ejo naa siwaju di ojo kefa osu kejila odun yi (-06-12-2012).

No comments:

Post a Comment