11/30/2012

Kayefi Nla: 'Bawo ni mo se le dekun ibalopo bi toko-taya ti o n waye laarin emi ati aburo oko mi?'


Mo lero wipe o ti wa to gee bayi, nitori wipe o ti wa di iba isele baraku fun mi bayi de ibi wipe bi oko mi ba wa ninu ile gan, emi ati aburo oko mi a ma sare 'gbose' ara wa wo ni kanmo-nkebe. Iberu okan mi bayi wa ni wipe bi a ba n ba lo bayi, oko mi ko ni pe ti yoo fi fura ohun ti o n sele laarin emi ati aburo re.

Akoni olokiki ninu ere lede Yoruba, Akin Akin Ogungbe ti dagbere f'aye

Erin wo! Ajanaku sun bi oke, ojogbon akoni olokiki ninu ere lede Yoruba fun opolopo odun seyin, Akintola Ogungbe ni a gbo wipe o ti ta teru nipa.

11/27/2012

Iyawo pe oko lejo, o ni ko ba oun ni ajosepo gege bi tokotaya fun odun meewa bayi


Iyawo, Saratu Haruna ni o wo oko re, Isa Mainika wa sile ejo ni ojo aje 26-11-2012 niwaju adajo ni ile ejo ti Sharia keji ti ipinle Kaduna ti o wa ni Magajin Gari wipe oko ti fi eto ibalopo gege bi lokolaya dun oun lati odun keewa si asiko ti a wa yii. Haruna ti n gbe Kawo, ni ijoba ibile Ila oorun ti ilu Kaduna so yanya niwaju ile ejo wipe oun o tire ni ife si ajosepo mo gegebi lokolaya laarin oun ati oko oun mo.

11/12/2012

ARA MEERIRI NI ORILE EDE THAILAND: EFON BI OMO TO JO OMO ENIYAN



Ni orile ede Thailand, eranko ti oruko re nje Efon (Bufallo) lati gbo wipe o bi omo tuntun to ri gele bi omo eniyan.

LAM ADESINA TA TERU NPA NI OMO ODUN METALELAADORIN



Awaye iku kan o si, orun nikan lare mabo. Iku to pa eni ti o ti fi gba kan ri je gomina ipinle Oyo, Alhaji Lamidi Onaolapo Adesina je adanu nla lo je fun ipinle Oyo lapapo ati paapaa julo laarin awon omo egbe oselu ACN ni ipile Oyo.

11/09/2012

Munachi Abii: Se aye jije naa ni eleyi?


Ejowo, iru owe yoruba wo lo ye fun iru aworan yii? Arabinrin yii ni oruko re n je Munachi Abii, o sese di
omo odun meedogbon ni o. N je iru imura bi ti were yii wa bojumu to ni awujo wa yii? Bo ya ko ba ti e wule bo tan pata-pata ni ki gbogbo aye le ri gbogbo oun ti o ta.

O mu mi ran ti orin kan ti a ma n ko fun iru eni ti o ba mura bayi ni aarin

Omobinrin Fasiti Ibadan gbe majele je nitori okunrin


Omobinrin kan ni ile iwe giga vasiti ti ilu Ibadan gbe bleach Hypo mu ni ojo isinmi ti se ojo kerin, osu kokanla, odun 2012 nitori wipe oko afesona re so wipe oun o se mo. Omobinrin yii ni agbo wipe o wa ni ipele olodun kinni ni  eka imo eto eko ti awon oloyinbo n pe ni Faculty of Art ni ile eko giga vasiti naa.

Ni akoko yii naa si ni awon omo ile eko giga yii n se idanwo won ti saa eto eko